ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 6/1 ojú ìwé 16-17
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2017
  • Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • Idi Tí A Fi Gbọdọ Mọ Orukọ Ọlọrun
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Bí O Ṣe Lè Mọ Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 6/1 ojú ìwé 16-17

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.

1. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fún ara rẹ̀ lórúkọ?

Ó dájú pé orúkọ rẹ ni wàá fẹ́ kí àwọn èèyàn máa fi pè ọ́ dípò kí wọ́n kàn máa pè ọ́ ní àwọn orúkọ oyè bí “ọkùnrin,” “ọ̀gbẹ́ni,” “ìyáàfin” tàbí “obìnrin.” Orúkọ rẹ máa jẹ́ kí àwọn èèyàn lè dá ọ mọ̀ yàtọ̀ sí ẹlòmíì. Àwọn èèyàn máa ń fi orúkọ oyè bí “Olúwa Ọba Aláṣẹ,” “Ọlọ́run Olódùmarè,” àti “Ẹlẹ́dàá Atóbilọ́lá” pe Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 15:2; 17:1; Oníwàásù 12:1) Àmọ́ ó sọ orúkọ ara rẹ̀ fún wa, ká lè mọ̀ ọ́n, ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Ka Sáàmù 83:18.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn atúmọ̀ Bíbélì kan ti fi orúkọ oyè bí “Ọlọ́run” àti “Olúwa” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run nínú ìtumọ̀ Bíbélì wọn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú àwọn ìwé Bíbélì ti èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fọwọ́ kọ. Èyí fi hàn gbangba gbàǹgbà pé Ọlọ́run ń fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ òun.—Ka Aísáyà 12:4.

2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run?

Mímọ orúkọ Ọlọ́run ju pé kéèyàn kàn lè pe orúkọ rẹ̀ jáde lẹ́nu lọ. Mímọ orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí pé kéèyàn sún mọ́ ọn tímọ́tímọ́. Orúkọ náà, Jèhófà túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Ìtumọ̀ orúkọ yìí fi hàn pé Ọlọ́run yóò ṣe ohunkóhun tó bá yẹ láti lè mú ète rẹ̀ ṣẹ. Torí náà, ẹni tó bá mọ orúkọ Ọlọ́run lóòótọ́, gbọ́dọ̀ gbà pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Sáàmù 9:10) Ìgbàgbọ́ tí àwọn tó mọ orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń lò ó ní, máa ń mú kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e, kí wọ́n sì fi ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ ṣáájú ohun gbogbo ní ìgbésí ayé wọn. Jèhófà Ọlọ́run sì máa dáàbò bo irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.—Ka Sáàmù 91:14.

3. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ òun?

Jèhófà fẹ́ kí àwọn èèyàn fi orúkọ òun mọ òun torí ìyẹn máa ṣe wọ́n láǹfààní púpọ̀. Ó máa jẹ́ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. Abájọ tí Jèhófà fi fẹ́ ká kéde orúkọ òun fáyé gbọ́!—Ka Jòhánù 17:3; Róòmù 10:13, 14.

Jésù mú kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run bó ṣe ń kọ́ wọn nípa ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, àwọn òfin rẹ̀ àti àwọn ìlérí rẹ̀. Lóde òní bákàn náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù náà ń bá a lọ láti jẹ́ kí àwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè mọ orúkọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ti Jésù. Ṣe ni wọ́n sì fìmọ̀ ṣọ̀kan lẹ́nu iṣẹ́ yẹn gẹ́gẹ́ bí “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ [Ọlọ́run].”—Ka Ìṣe 15:14; Jòhánù 17:26.

4. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe orúkọ ara rẹ̀ lógo?

Jèhófà fẹ́ ṣe orúkọ ara rẹ̀ lógo torí pé àwọn èèyàn ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn kan sọ pé òun kọ́ ló dá ohun gbogbo àti pé kò sídìí fún wa láti máa ṣègbọràn sí i. Àwọn míì sọ pé kò bìkítà nípa wa àti pé òun ló ń fa ìyà tó ń jẹ aráyé. Ṣe ni irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. Àmọ́, ìyẹn kò ní máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí láé. Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn tó tàbùkù sí orúkọ rẹ̀ run.—Ka Sáàmù 83:17, 18.

Jèhófà máa ṣe orúkọ ara rẹ̀ lógo nígbà tí Ìjọba rẹ̀ bá fòpin sí gbogbo ìṣàkóso èèyàn, tó sì mú àlàáfíà àti ààbò gbilẹ̀ kárí ayé. (Dáníẹ́lì 2:44) Láìpẹ́, gbogbo èèyàn yóò mọ̀, bí wọ́n fẹ́ bí wọ́n kọ̀, pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.—Ka Ìsíkíẹ́lì 36:23; Mátíù 6:9.

Kí ló wá yẹ kó o ṣe báyìí? Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí o sì máa dara pọ̀ mọ́ àwọn tó fẹ́ràn Jèhófà Ọlọ́run, kí o bàa lè sún mọ́ Ọlọ́run. Nígbà tí Jèhófà bá ṣe orúkọ ara rẹ̀ lógo, ó máa rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́.—Málákì 3:16.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí  1 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Orúkọ Ọlọ́run rèé nínú ìwé Bíbélì ti èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fọwọ́ kọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́