ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 9/1 ojú ìwé 3
  • Àìmọye Aláìṣẹ̀ Ló Ti Ṣègbé!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àìmọye Aláìṣẹ̀ Ló Ti Ṣègbé!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Kẹta: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Jẹ́ Kí Ìyà Máa Jẹ Mí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2020
  • Ìgbà Tí Ìyà Kò Ní Sí Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà Á Nígbà Tí Àjálù Bá Wáyé?
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 9/1 ojú ìwé 3
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀: KÍ NÌDÍ TÍ ÌYÀ FI PỌ̀ LÁYÉ? ÌGBÀ WO LÓ MÁA DÓPIN?

Àìmọye Aláìṣẹ̀ Ló Ti Ṣègbé!

Ọmọdébìnrin kan tó ń jẹ́ Noelle lọ́yàyà gan-an, ó sì fẹ́ràn láti máa ya àwòrán. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tó ṣeré lọ sí ẹ̀yìnkùlé ilé wọn, ó ré sínú omi tí wọ́n máa ń lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀. Bó ṣe kú sómi nìyẹn o, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀sẹ̀ méjì péré ló kù kó pé ọmọ ọdún mẹ́rin.

Ní December 14, 2012, ẹnì kan yìnbọn pa àwọn ọmọdé ní ilé ìwé kan ní ìpínlẹ̀ Connecticut tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lára wọn ni Charlotte, Daniel, Olivia àti Josephine. Àwọn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn lọ, ogún [20] nínú wọn ló sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà sí méje. Nígbà tí ààrẹ orílẹ̀-èdè náà, ìyẹn Obama ń dárúkọ àwọn ọmọ yìí níbi ìsìnkú wọn, ó sọ fún àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ pé: “Irú àjálù báyìí gbọ́dọ̀ dópin.”

Ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Bano àti ìdílé rẹ̀ ṣí kúrò ní orílẹ̀-èdè Ìráàkì lọ sí orílẹ̀-èdè Norway lọ́dún 1996. Ó ṣeni láàánú pé Bano wà lára àwọn mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [77] tí alákatakítí òṣèlú kan dá ẹ̀mí wọn légbodò ní July 22, 2011. Ọkùnrin yẹn tún ń fọ́nnu pé: “Ó yẹ kí n tọrọ àforíjì . . . pé mi ò pa jù ìwọ̀nba èèyàn yìí lọ.”

Irú àwọn ìròyìn tó ń bani lọ́kàn jẹ́ yìí kì í ṣe tuntun, àìmọye irú wọn la máa ń gbọ́ lójoojúmọ́ kárí ayé. Ẹ wo ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn tó ti bá àwọn èèyàn nítorí ìjàǹbá, ìwà ọ̀daràn, ogun, ìpániláyà, àjálù àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míì lóríṣiríṣi! Wàhálà àti ìdààmú pọ̀ nínú ayé, àìmọye aláìṣẹ̀ ló ń jìyà, tí ikú sì ń pa dà nù. Tá a bá sì wádìí ohun tó fà á, ko sí ìdí kan tó ṣe gúnmọ́ tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀.

Àwọn kan máa ń dá Ọlọ́run lẹ́bi, èrò wọn ni pé ọ̀rọ̀ àwa èèyàn kò já mọ́ nǹkan kan lójú Ẹlẹ́dàá. Àwọn míì tiẹ̀ rò pé Ọlọ́run kúkú ń rí ìyà tó ń jẹ wá, àmọ́ ńṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ máà dá sí ọ̀rọ̀ wa. Ìgbàgbọ́ àwọn míì sì ni pé kádàrá ni gbogbo àjálù tó ń ṣẹlẹ̀. Oríṣiríṣi nǹkan ni àwọn èèyàn ń sọ nípa kókó yìí. Ibo la ti lè rí àlàyé tó tẹ́ni lọ́rùn, tó sì ṣeé gbára lé lórí ọ̀rọ̀ yìí? Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa wo ohun tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ohun tó fa ìyà tó ń jẹ aráyé àti bí ìyà yìí ṣe máa dópin.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́