KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN
Ǹjẹ́ O Máa Ń Ṣe Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́?
Ká sọ pé o rí àjèjì kan, ǹjẹ́ o lè sọ fún un pé: “Ohunkóhun tó o bá fẹ́, ìwọ ṣáà ti sọ fún mi, inú mi á dùn láti ṣe é fún ẹ láìjáfara”? Kò dájú pé wàá sọ bẹ́ẹ̀, àmọ́ á rọrùn fún ẹ láti sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́, torí pé ọ̀rẹ́ àtọ̀rẹ́ máa ń ran ara wọn lọ́wọ́, ẹnì kìíní sì máa ń ṣe ohun tó máa múnú ẹnì kejì dùn.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó máa múnú àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ dùn. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì Ọba tí òun náà jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa. . . . Wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ!” (Sáàmù 40:5) Pabanbarì rẹ̀ ni pé oore Ọlọ́run kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, títí kan àwọn tí kò mọ̀ ọ́n pàápàá, gbogbo wọn pátá ló ń fi ‘oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.’—Ìṣe 14:17.
Ó máa ń rọ̀ wá lọ́rùn láti ṣoore fún àwọn tá a fẹ́ràn tá a sì kà sí
Jèhófà ń ṣe ipa tiẹ̀ láti ṣe ohun tó máa múnú gbogbo ẹ̀dá dùn, torí náà gbogbo ẹní tó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó máa “mú ọkàn-àyà” rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11) Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tó máa múnú Ọlọ́run dùn? Bíbélì sọ fún wa, ó ní: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” (Hébérù 13:16) Ṣé ohun tá a wa ń sọ ni pé béèyàn bá ṣáà ti ń ṣoore, tó sì lawọ́, ó parí náà nìyẹn?
Bíbélì sọ pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu [Ọlọ́run] dáadáa.” (Hébérù 11:6) Bí àpẹẹrẹ, ìgbà tí “Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà,” ló tó di “Ọ̀rẹ́ Jèhófà.” (Jákọ́bù 2:23) Jésù pàápàá jẹ́rìí sí i pé a gbọ́dọ̀ “lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run” bá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run bù kún wa. (Jòhánù 14:1) Báwo wá la ṣe lè ní irú ìgbàgbọ́ tó máa jẹ́ kí Ọlọ́run fà wá mọ́ra bí ọ̀rẹ́ rẹ̀? A gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Èyí ló máa jẹ́ ká ní “ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀,” àá sì mọ bí a ṣe lè “wù ú dáadáa.” Bí ìmọ̀ wa nípa Jèhófà ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tá a sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò láyé wa, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i, Jèhófà náà á sì túbọ̀ sún mọ́ wa.—Kólósè 1:9, 10.