Ǹjẹ́ O Mọyì Ohun Tí O Ti Rí Gbà?
‘Àwa gba ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kí àwa bàa lè mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti fi fún wa pẹ̀lú inú rere.’—1 KỌ́R. 2:12.
1. Kí lohun tí àwọn èèyàn sábà máa ń sọ?
ÀWỌN èèyàn sábà máa ń sọ pé: ‘Èèyàn kì í mọyì ohun tó ní àfi tó bá pàdánù rẹ̀.’ Ǹjẹ́ ìwọ náà gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Téèyàn bá láwọn nǹkan kan láti kékeré, ó ṣeé ṣe kéèyàn má fi bẹ́ẹ̀ mọyì wọn lóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tí wọ́n bá tọ́ nílé ọlá lè má ka ọ̀pọ̀ nǹkan tó ní sí bàbàrà. Bó ṣe rí fáwọn ọ̀dọ́ mí ì nìyẹn, bóyá nítorí àìní ìrírí, wọn kò tí ì fi bẹ́ẹ̀ mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé.
2, 3. (a) Kí làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ yẹra fún? (b) Kí ló máa jẹ́ ká lè mọyì ohun tá a ti rí gbà?
2 Tí o bá jẹ́ ọ̀dọ́, tí ọjọ́ orí rẹ sì wà láàárín ọdún mẹ́tàlá sí mẹ́tàlélógún, kí ló ṣe pàtàkì sí ẹ? Nǹkan tara ni ọ̀pọ̀ nínú ayé yìí gbájú mọ́, irú bí owó oṣù tó jọjú, ilé tó dára tàbí bí wọ́n ṣe máa ní oríṣiríṣi ẹ̀rọ ìgbàlódé. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan yìí nìkan lèèyàn gbájú mọ́, a jẹ́ pé ohun pàtàkì kan ṣì wà tá ò fiyè sí, ìyẹn sì ni ọrọ̀ tẹ̀mí. Ó ṣeni láàánú pé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lónìí ò tiẹ̀ tíì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọrọ̀ tẹ̀mí yìí. Ẹ̀yin ọ̀dọ́ tí àwọn òbí Kristẹni tọ́ dàgbà gbọ́dọ̀ kíyè sára kó má di pé ẹ kò ní mọyì ogún tẹ̀mí tí ẹ rí gbà. (Mát. 5:3) Tó o bá fi ogún tẹ̀mí yìí tàfàlà, àbájáde rẹ̀ lè burú jáì, èyí tó ṣeé ṣe kó ṣàkóbá fún ẹ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ.
3 Àmọ́, tí o kò bá fẹ́ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ọwọ́ ẹ ló kù sí. Kí ló máa jẹ́ kó o lè máa ṣìkẹ́ ogún tẹ̀mí tó o ní? Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ látinú Bíbélì tó máa jẹ́ ká mọ ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti mọyì ogún tẹ̀mí tá a ní. Àwọn àpẹẹrẹ tá a máa jíròrò máa jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ mọyì ohun tí wọ́n ní nípa tẹ̀mí, bákan náà, á ran gbogbo Kristẹni lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣìkẹ́ ogún tẹ̀mí tí wọ́n ti rí gbà.
WỌN KÒ MỌYÌ OHUN TÍ WỌ́N RÍ GBÀ
4. Kí ni 1 Sámúẹ́lì 8:1-5 jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn ọmọkùnrin Sámúẹ́lì?
4 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tí wọ́n rí ogún tẹ̀mí gbà àmọ́ tí wọn kò mọyì rẹ̀. Èyí wáyé nínú ìdílé wòlíì Sámúẹ́lì, ẹni tó sin Jèhófà láti ìgbà ọmọdé rẹ̀, ó sì ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (1 Sám. 12:1-5) Sámúẹ́lì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ tó yẹ kí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ìyẹn Jóẹ́lì àti Ábíjà tẹ̀ lé. Àmọ́, wọn ò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bàbá wọn, wọ́n sì di èèyàn burúkú. Bíbélì sọ fún wa pé wọn ò dà bí bàbá wọn, ńṣe ni wọ́n ń “yí ìdájọ́ po.”—Ka 1 Sámúẹ́lì 8:1-5.
5, 6. Kí ni ìgbẹ̀yìn àwọn ọmọkùnrin Jòsáyà àti ọmọ-ọmọ rẹ̀?
5 Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọkùnrin Jòsáyà Ọba. Jòsáyà fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà. Nígbà tí wọ́n rí ìwé Òfin Ọlọ́run, tí wọ́n sì kà á fún Jòsáyà, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti fi àwọn ìtọ́ni Jèhófà sílò. Ó fòpin sí ìbọ̀rìṣà àti ìbẹ́mìílò ní ilẹ̀ náà, ó sì rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n ṣègbọràn sí Jèhófà. (2 Ọba 22:8; 23:2, 3, 12-15, 24, 25) Ẹ ò rí i pé ogún tẹ̀mí tó ṣeyebíye ni àwọn ọmọ rẹ̀ rí gbà! Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ta àti ọmọ-ọmọ rẹ̀ kan ló pa dà di ọba, àmọ́ kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó mọyì ogún tẹ̀mí tí bàbá wọn fi sílẹ̀ fún wọn.
6 Jèhóáhásì ló jọba tẹ̀ lé Jòsáyà, àmọ́ ó ṣe “ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.” Oṣù mẹ́ta péré ló fi wà lórí oyè kó tó di pé Fáráò kan nílẹ̀ Íjíbítì jù ú sẹ́wọ̀n, ó sì kú sí oko ẹrú. (2 Ọba 23:31-34) Lẹ́yìn náà, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Jèhóákímù ṣàkóso fún ọdún mọ́kànlá. Òun náà ò mọyì ogún tẹ̀mí tó rí gbà látọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀. Torí ìwàkiwà tó kún ọwọ́ Jèhóákímù, Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “Bí a ṣe ń sin akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni a ó sin ín.” (Jer. 22:17-19) Kò sí èyí tó sàn nínú Sedekáyà ọmọ Jòsáyà àti Jèhóákínì ọmọ-ọmọ Jòsáyà táwọn náà pa dà jọba. Wọn ò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jòsáyà ní ti bó ṣe sin Jèhófà lọ́nà tó tọ́.—2 Ọba 24:8, 9, 18, 19.
7, 8. (a) Báwo ni Sólómọ́nì ṣe fi ogún tẹ̀mí rẹ̀ ṣòfò? (b) Kí la kọ́ lára àwọn tí Bíbélì mẹ́nu kàn pé wọ́n fi ogún tẹ̀mí wọn ṣòfò?
7 Sólómọ́nì Ọba jogún ọ̀pọ̀ nǹkan lọ́dọ̀ Dáfídì bàbá rẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì wá látinú ìdílé tí wọ́n ti fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run, ó sì ṣe dáadáa nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá kò mọyì rẹ̀ mọ́. Bíbélì sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì ń darúgbó lọ pé àwọn aya rẹ̀ alára ti tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn; ọkàn-àyà rẹ̀ kò sì pé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn-àyà Dáfídì baba rẹ̀.” (1 Ọba 11:4) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Sólómọ́nì pàdánù ojú rere Jèhófà.
8 Ó ṣeni láàánú pé, àwọn ọkùnrin yìí tí wọ́n wá láti ilé rere, tí wọ́n sì tún láǹfààní láti ṣe ohun tí ó tọ́ fi ogún tẹ̀mí wọn ṣòfò! Àmọ́ o, kì í ṣe gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tí Bíbélì ròyìn ló jẹ́ àpẹẹrẹ búburú. Bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe gbogbo ọ̀dọ́ òde òní ni kò mọyì ogún tẹ̀mí wọn. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀dọ́ mélòó kan táwọn ọ̀dọ́ Kristẹni lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere wọn.
WỌ́N MỌYÌ OHUN TÍ WỌ́N RÍ GBÀ
9. Báwo làwọn ọmọ Nóà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
9 Àpẹẹrẹ àtàtà ni àwọn ọmọ Nóà jẹ́. Ọlọ́run pàṣẹ fún bàbá wọn pé kó kan áàkì, kó sì kó ìdílé rẹ̀ sínú rẹ̀. Ó hàn kedere pé inú àwọn ọmọ Nóà dùn láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ó dájú pé wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú bàbá wọn. Wọ́n jọ kan áàkì náà, wọ́n sì wọ inú rẹ̀. (Jẹ́n. 7:1, 7) Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 7:3 sọ pé wọ́n kó àwọn ẹranko wọlé sínú áàkì náà “láti pa ọmọ mọ́ láàyè lórí gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.” Àwọn ẹ̀dá èèyàn náà sì rí ìgbàlà. Jèhófà dá ẹ̀mí àwọn ọmọ Nóà sí torí pé wọn fọwọ́ pàtàkì mú ohun tí wọ́n ti rí gbà lọ́dọ̀ bàbá wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún láǹfààní láti mú kí ìjọsìn tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun lórí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ti fọ̀ mọ́.—Jẹ́n. 8:20; 9:18, 19.
10. Báwo làwọn ọ̀dọ́kùnrin Hébérù mẹ́rin náà ṣe fi hàn pé àwọn mọyì òtítọ́ tí wọ́n ti kọ́?
10 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún, àwọn ọ̀dọ́kùnrin Hébérù mẹ́rin fi hàn pé àwọn mọ ohun tó ṣe pàtàkì. Wọ́n kó Hananáyà, Míṣáẹ́lì, Asaráyà àti Dáníẹ́lì lọ sí Bábílónì ní 617 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Wọ́n dáa lọ́mọkùnrin, ọpọlọ wọn sì jí pépé, ó máa rọrùn fún wọn láti máa gbé ìgbé ayé táwọn ará Bábílónì ń gbé. Àmọ́, wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tí wọ́n ṣe fi hàn pé wọ́n rántí ogún tẹ̀mí wọn, wọn kò gbàgbé ohun tí wọ́n ti kọ́. Jèhófà bù kún àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jìngbìnnì torí pé wọ́n rọ̀ mọ́ ohun tí wọ́n ti kọ́ nípa ìjọsìn tòótọ́ láti kékeré wọn.—Ka Dáníẹ́lì 1:8, 11-15, 20.
11. Báwo làwọn míì ṣe jàǹfààní nínú ọ̀pọ̀ ohun tẹ̀mí tí Jésù kọ́ lọ́dọ̀ Baba rẹ̀?
11 Àwọn àpẹẹrẹ réré tá à ń gbé yẹ̀ wò kò ní kún tó láì mẹ́nu kan àpẹẹrẹ Jésù, Ọmọ Ọlọ́run. Ó gba ọ̀pọ̀ nǹkan lọ́dọ̀ Baba rẹ̀, ó sì mọyì rẹ̀ gan-an. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé ó mọyì àwọn ohun tó tí kọ́ lọ́dọ̀ Baba rẹ̀, ó sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.” (Jòh. 8:28) Jésù fẹ́ káwọn míì náà jàǹfààní nínú ohun tó ti rí gbà. Ó sọ fún ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn kan pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:18, 43) Ó jẹ́ káwọn olùgbọ́ rẹ̀ rí ìdí tí kò fi yẹ kí wọ́n jẹ́ “apá kan ayé,” torí pé ayé lápapọ̀ kò mọyì àwọn ohun tẹ̀mí.—Jòh. 15:19.
MỌYÌ OHUN TÓ O TI RÍ GBÀ
12. (a) Báwo ni 2 Tímótì 3:14-17 ṣe kan ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lónìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ Kristẹni bi ara wọn?
12 Bíi tàwọn ọ̀dọ́kùnrin tá a ti jíròrò nípa wọn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òbí tó ń sin Jèhófà Ọlọ́run tọkàntọkàn ló tọ́ ìwọ náà dàgbà. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Tímótì bá ipò tó o wà mu. (Ka 2 Tímótì 3:14-17.) Àwọn òbí rẹ ló kọ́ ọ nípa Ọlọ́run tòótọ́, tí wọ́n sì jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè múnú rẹ̀ dùn. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé láti ìgbà tó o ti wà lọ́mọdé jòjòló làwọn òbí rẹ ti ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó dájú pé èyí ti mú kó o di “ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù,” ó sì ti jẹ́ kó o “gbára dì pátápátá” láti ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Ìbéèrè pàtàkì kan ni pé, Ṣé wàá fi hàn pé o mọyì àwọn ohun tó o ti gbà yìí? Èyí lè gba pé kó o yẹ ara rẹ wò dáadáa. Ronú lórí àwọn ìbéèrè bíi: ‘Báwo ló ṣe rí lára mi pé mo wà lára ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́? Báwo ló ṣe rí lára mi pé èmi náà wà lára àwọn èèyàn díẹ̀ kan lórí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run mọ̀? Ǹjẹ́ mo mọyì àǹfààní ńlá tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí mo ní pé mo mọ òtítọ́?’
Bawo lo se ri lara re pe o wa lara ogooro awon elerii ti won je olooto? (Wo ipinro 9, 10, 12)
13, 14. Ìdẹwò wo làwọn ọ̀dọ́ kan máa ń kojú? Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu tí wọ́n bá jẹ́ kó borí wọn? Sọ àpẹẹrẹ kan.
13 Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ló tọ́ àwọn ọ̀dọ́ kan dàgbà, àmọ́ àwọn ọ̀dọ́ yìí lè máà rí i pé ìyàtọ̀ gedegbe ló wà láàárín Párádísè tẹ̀mí táà ń gbádùn báyìí àti ayé Sátánì tó wà nínú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí. Àwọn míì ti lọ sínú ayé torí pé wọ́n fẹ́ mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí nínú ayé Sátánì. Àmọ́ ṣé wàá mọ̀ọ́mọ̀ lọ kó sẹ́nu ọkọ̀ tó ń sáré bọ̀ torí o kàn fẹ́ mọ bí ìrora yẹn ṣe máa pọ̀ tó tàbí bó o ṣe máa fara pa tó? Ó dájú pé o ò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀! Lọ́nà kan náà, kò sídìí fún wa láti lọ jìn sínú “kòtò ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀ kan náà tí ó kún fún ìwà wọ̀bìà” nínú ayé yìí torí pé a kàn fẹ́ mọ bó ṣe máa roni lára gógó tó.—1 Pét. 4:4.
14 Inú ìdílé Kristẹni ni wọ́n ti tọ́ ọ̀dọ́kùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gener dàgbà, ó sì ń gbé ní ilẹ̀ Éṣíà. Ó ṣèrìbọmi ní ọmọ ọdún méjìlá. Àmọ́, kò tíì pé ọmọ ogún ọdún tí ọkàn rẹ̀ ti ń fà sí ọ̀nà ayé. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ kí n máa ṣe ohun tó wù mi báwọn èèyàn ayé ti máa ń ṣe.” Gener bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá. Nígbà tó fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í hu àwọn ìwà kan tó kọ́ lára ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ tó ń bá rìn. Ó ń mutí, ó sì máa ń ṣépè bíi tiwọn. Gener kì í wálé bọ̀rọ̀ tí òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá ti lọ gbá bọ́ọ̀lù tí wọ́n máa ń fi ọ̀pá gbá lórí tábìlì àti géèmù oníwà ipá lórí kọ̀ǹpútà. Àmọ́, nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ṣàgbẹ̀ lójú yòyò lásán làwọn ohun tó dà bíi pé ó fani mọ́ra nínú ayé yìí. Asán lórí asán ni gbogbo rẹ̀. Nígbà tó pa dà sínú ìjọ, ó sọ pé: “Mo ṣì ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro, àmọ́ ìbùkún Jèhófà ju àwọn ìṣòro náà lọ fíìfíì.”
15. Kí làwọn ọ̀dọ́ tí àwọn òbí wọn kì í ṣe Kristẹni lè máa ronú lé lórí?
15 Àwọn ọ̀dọ́ míì wà tí wọ́n ń sin Jèhófà àmọ́ táwọn òbí wọn kì í ṣe Kristẹni. Tó o bá jẹ́ ọ̀kan lára wọn, ìwọ wo àǹfààní ńlá tó ò ń gbádùn torí pé o mọ Ẹlẹ́dàá, tí o sì ń sìn ín! Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló wà láyé. Torí náà, ìbùkún àgbàyanu ló jẹ́ láti wà lára àwọn tí Jèhófà fìfẹ́ fà sún mọ́ ara rẹ̀, tó sì jẹ́ kí wọ́n lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. (Jòh. 6:44, 45) Tá a bá pín gbogbo èèyàn tó wà láyé sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, tí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan, ẹnì kan ṣoṣo péré nínú ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan ló ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́, o sì jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Ǹjẹ́ ìyẹn ò tó ohun ayọ̀ fún wa, láìka ọ̀nà yòówù ká a gbà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ sí? (Ka 1 Kọ́ríńtì 2:12.) Gener sọ pé: “Ńṣe ni irun ara mi máa ń dìde tí mo bá ronú lórí àǹfààní tí mo ní. Kí ni mo jẹ́ tí Jèhófà Olùṣẹ̀dá ayé àtọ̀run, fi dá mi mọ̀?” (Sm. 8:4) Arábìnrin kan tí òun àti Gener jọ wá láti àdúgbò kan náà sọ pé: “Inú akẹ́kọ̀ọ́ máa ń dùn gan-an tí olùkọ́ rẹ̀ bá dá a mọ̀ yàtọ̀ láàárín àwọn ọmọléèwé tó kù. Mélòómélòó wá ni kí Jèhófà tó jẹ́ Atóbilọ́lá Olùkọ́ mọ ẹnì kan, ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ni èyí jẹ́!”
KÍ NI WÀÁ ṢE?
16. Ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu wo làwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lè ṣe lóde òní?
16 Tó o bá ro àǹfààní àgbàyanu tó o ní, ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí mú kó o túbọ̀ pinnu pé o ò ní kúrò láwùjọ ìwọ̀nba àwọn díẹ̀ tó ti fi ìgbésí ayé wọn ṣe ohun tó tọ́? Wàá tipa bẹ́ẹ̀ wà lára ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Èyí bọ́gbọ́n mu ju pé kó o kàn máa tẹ̀ lé àwọn ọ̀dọ́ inú ayé, táwọn náà kàn ń lọ gọ̀ṣú-gọ̀ṣú lẹ́yìn ayé yìí sínú ìparun.—2 Kọ́r. 4:3, 4.
17-19. Kí ló máa jẹ́ kó o ní èrò tó tọ́ nípa dídá yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé?
17 Òótọ́ kan ni pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn téèyàn bá dá yàtọ̀ nínú ayé. Àmọ́, tó o bá fara balẹ̀ ronú nípa rẹ̀, wàá rí i pé ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé ká dá yàtọ̀. Àpèjúwe kan rèé: Jẹ́ ká sọ pé ẹnì kan fẹ́ lọ sí Ìdíje Òlíńpíìkì. Ó dájú pé, ó gbọ́dọ̀ tayọ láàárín àwọn ojúgbà rẹ̀ kó tó lè láǹfààní yẹn. Ó ṣeé ṣe kó fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara rẹ̀, torí kò ní fẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ tàbí gba àkókò táá fi ṣe ìmúrasílẹ̀. Ohun míì tún ni pé, bó ṣe wù ú kó ta yọ láàárín àwọn ojúgbà rẹ̀ máa mú kó máa wáyè kó lè múra sílẹ̀ dáadáa, kọ́wọ́ rẹ̀ lè tẹ àfojúsùn rẹ̀.
18 Bí àwọn èèyàn ayé ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn fi hàn pé wọn kì í ro ti ọ̀la mọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́, tó o bá wò ré kọjá ohun tó ò ń rí báyìí, ìyẹn ni pé tó o dá yàtọ̀ nínú ayé, tí o kò sì bá wọn lọ́wọ́ sáwọn ìwà tí kò tọ́ àtèyí tó lè ba àjọṣe ìwọ àti Jèhófà jẹ́, wàá lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (1 Tím. 6:19) Arábìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tó o bá dúró ṣinṣin lórí ohun tí o gbà gbọ́, o kò ní kábàámọ̀ rẹ̀ láéláé. Ńṣe ló máa fi hàn pé o kò kọjú síbi tí ayé Sátánì kọjú sí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ṣe ló máa ṣe ẹ́ bíi pé ò ń rí Jèhófà Ọlọ́run tó ń fi ẹ́ yangàn, tó sì ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sí ẹ! Ìgbà yẹn ni inú tìẹ náà máa dùn pé o dá yàtọ̀!”
19 Tó bá jẹ́ pé ohun tọ́wọ́ èèyàn lè tẹ̀ báyìí nìkan lèèyàn gbájú mọ́, asán lórí asán ni ìgbésí ayé rẹ̀ máa já sí. (Oníw. 9:2, 10) Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, tó o sì ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó o fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe àti gbogbo ọdún tó ṣeé ṣe kó o lò láyé, ǹjẹ́ o ò rò pé ó bọ́gbọ́n mu tó o bá ṣọ́ra fún “rírìn gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ti ń rìn,” tó o sì gbé ìgbé ayé tí inú Ọlọ́run dùn sí?—Éfé. 4:17; Mál. 3:18.
20, 21. Tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́, kí ló ń dúró dè wá, àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
20 Tá a bá ṣèpinnu tó tọ́, a lè gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀ báyìí, ká sì láǹfààní láti “jogún ilẹ̀ ayé,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun. Ọ̀pọ̀ ìbùkún àgbàyanu ló wà nípamọ́ fún wa tá ò tiẹ̀ lè ronú kan gbogbo rẹ̀ tán báyìí. (Mát. 5:5; 19:29; 25:34) Ọlọ́run kì í kàn-án dédé fún wa ní nǹkan. Ó ń retí ohun kan látọ̀dọ̀ wa. (Ka 1 Jòhánù 5:3, 4.) Ohun tó sàn jù ni pé ká fi gbogbo ayé wa sin Jèhófà báyìí.
21 Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a ti rí ọ̀pọ̀ nǹkan gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run! A lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó péye, a sì ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa irú ẹni tó jẹ́ àtàwọn ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀. A láǹfààní láti máa jẹ́ orúkọ rẹ̀ àti Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Ọlọ́run ṣèlérí fún wa pé òun wà pẹ̀lú wa. (Sm. 118:7) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa, yálà ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, máa fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa. A lè ṣe èyí tá a bá ń gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó fi hàn pé ó wù wá gan-an láti máa fi ‘ògo fún un títí láé.’—Róòmù 11:33-36; Sm. 33:12.