ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 10/1 ojú ìwé 5
  • Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fẹ́ Ká Máa Gbàdúrà sí Òun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fẹ́ Ká Máa Gbàdúrà sí Òun
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run fẹ́ kó o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun.
  • Ọlọ́run fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.
  • Ó máa ǹ wu àwa èèyàn láti sún mọ́ Ọlọ́run.
  • Ṣé Ọlọ́run Ń Gbọ́ Àdúrà Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Sísún Mọ́ Ọlọrun Nínú Àdúrà
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 10/1 ojú ìwé 5

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀǸFÀÀNÍ WO LO MÁA RÍ TÓ O BÁ Ń GBÀDÚRÀ

Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fẹ́ Ká Máa Gbàdúrà sí Òun

Ọlọ́run fẹ́ kó o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun.

Bí ọ̀rẹ́ àtọ̀rẹ́ bá jọ ń sọ̀rọ̀ dáadáa, àárín wọ́n máa gún. Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run fẹ́ ká máa bá òun sọ̀rọ̀, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní: “Ẹ ó sì pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, èmi yóò sì fetí sí yín.” (Jeremáyà 29:12) Bó o ṣe ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, wàá “sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ [ẹ].” (Jákọ́bù 4:8) Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.” (Sáàmù 145:18) Bí a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run déédéé, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ máa túbọ̀ gún régé.

“Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.”​—Sáàmù 145:18

Ọlọ́run fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Jésù sọ pé: “Ta ni ọkùnrin náà láàárín yín, tí ọmọ rẹ̀ béèrè búrẹ́dì, òun kì yóò fi òkúta lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Tàbí, bóyá, òun yóò béèrè ẹja, òun kì yóò fi ejò lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Nítorí náà, bí ẹ̀yin . . . bá mọ bí a ṣe ń fi àwọn ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi àwọn ohun rere fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Mátíù 7:9-11) Torí náà, Ọlọ́run fẹ́ kó o gbàdúrà sí òun torí pé ‘ó bìkítà fún ẹ,’ ó sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. (1 Pétérù 5:7) Kódà, ó fẹ́ kó o sọ gbogbo ìṣòro rẹ fún òun. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.

Ó máa ǹ wu àwa èèyàn láti sún mọ́ Ọlọ́run.

Àwọn onímọ̀ nípa ìṣesí ẹ̀dá kíyè sí i pé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló máa ń fẹ́ gbàdúrà. Títí kan àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà.a Èyí fi hàn pé Ọlọ́run dá wa lọ́nà tó fi máa wù wá láti sún mọ́ ọn. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ọ̀nà kan tá a lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run ni pé ká máa gbàdúrà sí i déédéé.

Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run?

a Lọ́dún 2012, iléeṣẹ́ ìwádìí kan tó ń jẹ́ Pew Research Center ṣe ìwádìí kan nípa àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìwádìí náà fi hàn pé ẹnì kan nínú mẹ́wàá lára wọn máa ń gbàdúrà ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lóṣù.

Àwọn Nǹkan Wo La Lè Béèrè Nínú Àdúrà?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé a lè gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa ohunkóhun tó bá ń jẹ wá lọ́kàn. Torí náà, a lè gbàdúrà nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí:

  • Ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni mo jẹ́wọ́ fún ọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìṣìnà mi ni èmi kò sì bò mọ́lẹ̀.”—Sáàmù 32:5.

  • Ìdúpẹ́ “Ó dára láti máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà.”—Sáàmù 92:1.

  • Ìyìn “Ṣe ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún Jèhófà ní gbogbo ìgbà; ìgbà gbogbo ni ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi.”—Sáàmù 34:1.

  • Ìtọ́sọ́nà “Mú kí n máa rìn ní ipa ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ, nítorí tí mo ní inú dídùn sí i.”—Sáàmù 119:35.

  • Okun “Yíjú sí mi, kí o sì fi ojú rere hàn sí mi. Fi okun rẹ fún ìránṣẹ́ rẹ.” —Sáàmù 86:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́