ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp16 No. 6 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń dáhùn?
  • Ṣé ó ní ipò kan tá a gbọ́dọ̀ wà ká tó lè gbàdúrà?
  • Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ṣé Ọlọ́run Á Gbọ́ Àdúrà Mi?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Sísún Mọ́ Ọlọrun Nínú Àdúrà
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
wp16 No. 6 ojú ìwé 16
Obìnrin kan tó ń gbàdúrà

Ohun Tí Bíbélì Sọ?

Ṣé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń dáhùn?

KÍ LÈRÒ RẸ?

  • Ó máa ń dáhùn àdúrà gbogbo èèyàn

  • Àdúrà àwọn èèyàn díẹ̀ ló máa ń dáhùn

  • Kì í dáhùn àdúrà ẹnì kankan

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo . . . àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́.”​—Sáàmù 145:18.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Ọlọ́run kì í dáhùn àdúrà àwọn tó ń ṣe ohun tí kò fẹ́. (Aísáyà 1:15) Ṣùgbọ́n, wọ́n lè “mú àwọn ọ̀ràn tọ́” pẹ̀lú Ọlọ́run nípa yíyí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn pa dà sí rere.​—Aísáyà 1:18.

  • Kí Ọlọ́run tó lè dáhùn àdúrà ẹnì kan, ẹni náà gbọ́dọ̀ gbà á ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì.​—1 Jòhánù 5:14.

Ṣé ó ní ipò kan tá a gbọ́dọ̀ wà ká tó lè gbàdúrà?

ÀWỌN KAN GBÀ GBỌ́ PÉ àwọn gbọ́dọ̀ kúnlẹ̀ tàbí kí àwọn tẹrí ba tàbí kí wọ́n pa ọwọ́ pọ̀ nígbà tí àwọn bá ń gbàdúrà. Kí lèrò rẹ?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ọlọ́run ti gbọ́ àdúrà àwọn tó “jókòó” àti tàwọn tó “dìde dúró” nígbà tí wọ́n ń gbàdúrà. Ó sì ti gbọ́ àdúrà àwọn tó “wólẹ̀” àti tàwọn tó ‘tẹ eékún wọn ba.’ (1 Kíróníkà 17:16; 2 Kíróníkà 30:27; Ẹ́sírà 10:1; Ìṣe 9:40) Kò béèrè pé ká wà nípò kan pàtó nígbà tí a bà ń gbàdúrà kí òun tó lè gbọ́ wa.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. ​—Sáàmù 138:6.

  • O lè gbàdúrà ní oríṣiríṣi èdè, o sì tún lè gbàdúrà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.​—2 Kíróníkà 6:​32, 33; Nehemáyà 2:1-6.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 17 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́