ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w17 May ojú ìwé 31-32
  • “Wọ́n Fìtara Wàásù Pẹ̀lú Ìfẹ́ Ọkàn Tó Ju Ti Tẹ́lẹ̀ Lọ”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Wọ́n Fìtara Wàásù Pẹ̀lú Ìfẹ́ Ọkàn Tó Ju Ti Tẹ́lẹ̀ Lọ”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
w17 May ojú ìwé 31-32
Èrò rẹpẹtẹ nínú gbọ̀ngàn tí wọ́n ti ṣe àpéjọ ní Cedar Point, Ohio, lọ́dún 1922

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

“Wọ́n Fìtara Wàásù Pẹ̀lú Ìfẹ́ Ọkàn Tó Ju Ti Tẹ́lẹ̀ Lọ”

OHUN kan ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Friday kan lóṣù September 1922. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, ooru ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú nínú gbọ̀ngàn ńlá kan tí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] èèyàn pé jọ sí. Alága àpéjọ náà kéde pé mánigbàgbé ni àpéjọ yẹn máa jẹ́, àmọ́ bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jáde, kò sẹ́ni tó máa dí i lọ́wọ́ ṣùgbọ́n kò ní sí àyè fún un láti pa dà wọlé mọ́.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ ọ̀pọ̀ orin níbẹ̀rẹ̀ àpéjọ náà, Arákùnrin Joseph F. Rutherford bọ́ sórí pèpéle. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó pé jọ ni ara wọn ti wà lọ́nà láti gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ. Àmọ́, ṣe làwọn kan ń rìn lọ rìn bọ̀ nínú ooru yẹn. Olùbánisọ̀rọ̀ rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n wábi jókòó, kí wọ́n sì tẹ́tí sílẹ̀. Bí àsọyé náà ṣe ń lọ, kò dájú pé ẹnikẹ́ni kíyè sí aṣọ tí wọ́n ká jọ sí òkè téńté.

Àkòrí àsọyé Arákùnrin Rutherford ni “Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” Nǹkan bíi wákàtí kan àtààbọ̀ ló fi sọ̀rọ̀, tí ohùn rẹ̀ sì rinlẹ̀ nínú gbọ̀ngàn ńlá náà bó ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn wòlíì ìgbàanì tí wọ́n fìtara kéde Ìjọba Ọlọ́run láìbẹ̀rù. Nígbà tó máa parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó béèrè pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbà gbọ́ pé Ọba ògo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso?” Gbogbo àwọn tó pé jọ náà dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni!”

Arákùnrin Rutherford wá fìtara sọ pé, “Nígbà náà ẹ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, ẹ̀yin ọmọ Ọlọ́run tí í ṣe ẹni gíga jùlọ! Ẹ wò ó, Ọba náà ti ń ṣàkóso! Ẹ̀yin ni aṣojú tí ń polongo rẹ̀. Torí náà, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere.”

Ọ̀rọ̀ yẹn ló ń sọ lọ́wọ́, bó ṣe di pé aṣọ tí wọ́n ká jọ sókè téńté bẹ̀rẹ̀ sí í tú nìyẹn, táwọn èèyàn sì rí ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára rẹ̀, pé: “Ẹ Fọn Rere Ọba Náà àti Ìjọba Rẹ̀.”

Ray Bopp sọ pé: “Ńṣe ni àtẹ́wọ́ ń ró lọ́jọ́ náà.” Anna Gardner sọ bí “àtẹ́wọ́ táwọn ará pa ṣe mú káwọn igi ìrólé ibẹ̀ mì.” Fred Twarosh sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, ó ní: “Ṣe ni gbogbo wa dìde dúró lẹ́ẹ̀kan náà.” Evangelos Scouffas náà sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé agbára ńlá kan ṣàdédé gbé gbogbo wa dìde lórí ìjókòó wa, a dìde dúró, omijé sì lé ròrò sójú wa.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ tó wà ní àpéjọ yẹn ló ti ń polongo ìhìn rere Ìjọba náà ṣáájú ìgbà yẹn, àmọ́ ní báyìí, ṣe ni wọ́n wá rí àkọ̀tun ìdí láti máa wàásù. Ethel Bennecoff sọ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í “fìtara wàásù, ìfẹ́ ọkàn tí wọ́n sì fi ń ṣe iṣẹ́ náà wá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] ni Arábìnrin Odessa Tuck nígbà yẹn, lẹ́yìn tó kúrò ní àpéjọ yẹn, ó pinnu láti jẹ́ ìpè náà pé, ‘Ta ni yóò lọ?’ Ó sọ pé: “Mi ò mọ bí nǹkan ṣe máa rí. Àmọ́ ohun tí mo mọ̀ ni pé, mo fẹ́ dà bí Aísáyà tó sọ pé, ‘Èmi nìyí! Rán mi.’ ” (Aísá. 6:⁠8) Ralph Leffler sọ pé: “Ọjọ́ aláyọ̀ yìí gan-an la bẹ̀rẹ̀ sí í fọn rere Ìjọba náà, ìkéde yìí sì ti wá kárí ayé báyìí.”

Abájọ tí àpéjọ tá a ṣe lọ́dún 1922 ní Cedar Point, Ohio, fi jẹ́ mánigbàgbé nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà! George Gangas sọ pé, “Àpéjọ yẹn ni mo ti pinnu pé mi ò ní pa àpéjọ èyíkéyìí jẹ láé.” Bó sì ṣe rí náà nìyẹn, kò jọ pé ó pa àpéjọ kankan jẹ látìgbà yẹn. Arábìnrin Julia Wilcox sọ pé: “Mi ò lè sọ bí inú mi ṣe máa ń dùn tó nígbàkigbà tí wọ́n bá mẹ́nu kan àpéjọ Cedar Point tọdún 1922 nínú ìwé wa. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń sọ pé, ‘O ṣé o Jèhófà tó o jẹ́ kí n wà níbẹ̀.’ ”

Bíi tàwọn ará yìí, ọ̀pọ̀ wa náà máa ń rántí àpéjọ kan tá a gbádùn gan-an, tó mú ká túbọ̀ máa fìtara wàásù, ká sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa àti Jésù Ọba wa. Nígbàkigbà tá a bá rántí irú àpéjọ bẹ́ẹ̀, àwa náà máa ń sọ pé, “O ṣé o Jèhófà tó o jẹ́ kí n wà níbẹ̀.”

Àwọn Àmì Tó Ṣàjèjì

Gbogbo ibi táwọn èèyàn yíjú sí ni wọ́n ti ń rí ọ̀rọ̀ náà “ADV,” wọ́n gbé e kọ́ ara igi, ó wà lára ilé àti nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà! Ńṣe làwọn tó wá sí àpéjọ yẹn ń ronú ohun tó ṣeé ṣe kọ́rọ̀ náà túmọ̀ sí.a

“À ń rí káàdì funfun tí wọ́n so mọ́ àwọn ara òpó àtàwọn ẹnu ọ̀nà, wọ́n fi yíǹkì dúdú kọ ọ̀rọ̀ náà ADV gàdàgbà-gadagba sínú rẹ̀. A béèrè pé kí lọ̀rọ̀ náà dúró fún, àmọ́ ó jọ pé kò sẹ́ni tó mọ̀ ọ́n, bí wọ́n bá sì mọ̀ ọ́n, wọn ò fẹ́ sọ fún wa.”​—Edith Brenisen.

a “ADV” ni lẹ́tà mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà “Advertise” tá a tú sí “fọn rere.” Títí dòní, a ò rí fọ́tò àwọn àmì tí wọ́n lò nígbà yẹn nínú Àpamọ́ wa.

Jèhófà Gbọ́ Àdúrà Wọn Lọ́nà Ìyanu

Arthur àti Nellie Claus tètè dé síbi àpéjọ náà kí wọ́n lè jókòó sọ́wọ́ iwájú. Arthur sọ pé, “Mo fara balẹ̀ tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ náà.” Àmọ́, ṣàdédé ni inú bẹ̀rẹ̀ sí í run ún. Kò wù ú kó jáde, torí ó mọ̀ pé tóun bá jáde, òun ò ní lè wọlé mọ́. Nígbà tó fẹ́ jáde, ọ̀kan lára àwọn tó ń bójú tó èrò bi í pé, “Ṣé irú àsìkò yìí ló yẹ kó o jáde?” Àmọ́ Arthur kò lè mú un mọ́ra mọ́.

Nígbà tí Arthur ń pa dà, ó gbọ́ tí àtẹ́wọ́ ń ró nínú gbọ̀ngàn náà. Ó wá ibi tó lè dúró sí kó lè rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó wá ríbì kan tó lè gùn lọ sórí òrùlé ilé náà, tó ga tó nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rìndínlógún [16]. Lẹ́yìn náà, ó kọjá síbi ihò kan tó wà lórí òrùlé, ó sì gbabẹ̀ wọlé sí àjà ilé náà.

Nínú àjà yẹn, Arthur rí àwọn arákùnrin mélòó kan tí wọ́n ń wo olùbánisọ̀rọ̀ nísàlẹ̀. Torí kí wọ́n lè gé okùn tí wọ́n fi so aṣọ náà rọ̀ ni wọ́n ṣe wà níbẹ̀. Ẹ̀ẹ̀kan náà ló yẹ kí gbogbo wọn gé okùn yẹn, àmọ́ ọ̀bẹ tí wọ́n á lò ku ẹyọ kan. Wọn ò mọ ọgbọ́n tí wọ́n á dá sí i, wọ́n wá béèrè lọ́wọ́ Arthur bóyá ó ní ọ̀bẹ lápò. Inú wọn dùn nígbà tó sọ pé òun ní. Bí Arthur ṣe dara pọ̀ mọ́ wọn nìyẹn, wọ́n dúró dìgbà tó yẹ kí wọ́n gé okùn náà. Ìgbà tí Arákùnrin Rutherford bá sọ pé “Ẹ fọn rere!” lẹ́ẹ̀kejì ni wọ́n á ti ọ̀bẹ bọ okùn náà.

Àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà sọ bí aṣọ ńlá aláwọ̀ mẹ́ta tí wọ́n ká jọ náà ṣe rọra wálẹ̀. Àwòrán Jésù wà lára aṣọ náà.

Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn arákùnrin náà wá ṣàlàyé fún Arthur pé àkàbà làwọn fi gòkè. Àmọ́ torí pé wọ́n ti gbé àkàbà náà kúrò, àwọn ò lè sọ̀kalẹ̀ lọ mú ọ̀bẹ míì. Wọ́n gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí arákùnrin kan tó ní ọ̀bẹ lọ́wọ́ gòkè wá. Àwọn arákùnrin náà gbà pé bí Arthur ṣe wá yẹn fi hàn pé Jèhófà gbọ́ àdúrà àwọn lọ́nà ìyanu.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́