ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w19 June ojú ìwé 31
  • Àkájọ Ìwé Àtijọ́ Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àkájọ Ìwé Àtijọ́ Kan
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì Di Odindi Ìwé Ó Kúrò Ní Àkájọ Ìwé, Ó Di Ìwé Alábala
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • “Ìwé Orin Òkun” Ìwé Tí Wọ́n Kọ Láàárín Àkókò Méjì Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ọjọ́ Ìdájọ́ Ọlọ́run—Àbájáde Rẹ̀ Aláyọ̀!
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
w19 June ojú ìwé 31
Àkájọ ìwé Ein Gedi tí iná ti rà; àkájọ ìwé yìí kí wọ́n tó rí i ṣí

Àkájọ Ìwé Àtijọ́ Kan

Àkájọ ìwé tí iná ti rà, èyí tí wọ́n rí ní Ein Gedi kò ṣeé kà látọdún 1970 tí wọ́n ti ṣàwárí rẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, ẹ̀rọ ìgbàlódé 3-D scanner ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé apá kan ìwé Léfítíkù ló wà nínú rẹ̀, orúkọ Ọlọ́run sì wà níbẹ̀

LỌ́DÚN 1970, àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí àkájọ ìwé kan tí iná ti rà ní agbègbè Ein Gedi, tó wà nítòsí etíkun ìwọ̀ oòrùn Òkun Òkú, ìyẹn nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Ìgbà tí wọ́n ń hú àwókù sínágọ́gù kan tó jóná ni wọ́n rí àkájọ ìwé náà. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa abúlé tí sínágọ́gù náà wà run. Kò rọrùn láti ka àwọn ọ̀rọ̀ inú àkájọ ìwé náà torí bó ṣe rí, kódà wọn ò lè tú ìwé náà, torí tí wọ́n bá tú u, ó máa bà jẹ́. Àmọ́, nígbà tí wọ́n fi ẹ̀rọ ìgbàlódé tí wọ́n fi máa ń ṣàyẹ̀wò irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wò ó, ìyẹn 3-D scanner, wọ́n rí ohun tó wà nínú rẹ̀ kà. Àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé míì ti mú kó ṣeé ṣe láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀, kí wọ́n sì rí ohun tó wà nínú rẹ̀ kà.

Kí ni àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fi hàn nípa àkájọ ìwé náà? Wọ́n rí i pé àkájọ ìwé Bíbélì ni. Apá tó ṣeé kà níbẹ̀ fi hàn pé àwọn ẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Léfítíkù ló wà nínú rẹ̀. Lára ohun tó wà nínú ẹ̀ ni lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù. Ó jọ pé àárín ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni sí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ ọ̀rọ̀ inú ìwé náà, tó fi hàn pé òun ni àkájọ ìwé Bíbélì tó wà lédè Hébérù tó tíì pẹ́ jù táwọn awalẹ̀pìtàn rí lẹ́yìn èyí tí wọ́n ṣàwárí ní Qumran. Nínú ìwé The Jerusalem Post, tí Gil Zohar kọ, ó sọ pé: “Kó tó di pé wọ́n ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú àkájọ ìwé Léfítíkù tí wọ́n rí ní Ein Gedi, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan ló wà láàárín ìgbà tí wọ́n kọ àkájọ ìwé Òkun Òkú, ìyẹn lásìkò tí wọ́n ń kọ́ Tẹ́ńpìlì Kejì àti Aleppo Codex tí wọ́n kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹwàá Sànmánì Kristẹni.” Bí àwọn ọ̀mọ̀wé ṣe sọ, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àkájọ ìwé Léfítíkù yìí fi hàn pé Tórà táwọn Másórétì dà kọ “ṣì wà digbí láìní àbùkù bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti ṣe àdàkọ rẹ̀ tó sì ti wà fún ọ̀pọ̀ ọdún.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́