Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 29, 2011.
Báwo ni inú rere onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ṣe “sàn ju ìyè”? (Sm. 63:3) [w01 10/15 ojú ìwé 15, ìpínrọ̀ 17]
Kí ni Sáàmù 70 jẹ́ ká mọ̀ nípa Dáfídì? [w08 9/15 ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 4]
Kí ni Sáàmù 75:5 kìlọ̀ nípa rẹ̀? [w06 7/15 ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 2]
Ìgbà wo gan-an la lè retí pé kí Jèhófà gbọ́ àwọn àdúrà wa? (Sm. 79:9) [w06 7/15 ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 5]
Kí ni “àwọn nǹkan àṣírí” tí Sáàmù 90:7, 8 sọ nípa rẹ̀? [w01 11/15 ojú ìwé 12 sí 13, ìpínrọ̀ 14 sí 16]
Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Sáàmù 92:12-15, ojúṣe pàtàkì wo làwọn àgbàlagbà ní nínú ìjọ? [w04 5/15 ojú ìwé 13 sí 14, ìpínrọ̀ 14 sí 18]
Ṣé ọ̀rọ̀ tó wà ní Sáàmù 102:25-27 fi hàn pé ńṣe ni onísáàmù náà ń sọ pé ayé kò lè wà títí láé gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pinnu? (Jẹ́n. 1:28) [w08 4/1 ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 1]
Ẹ̀kọ́ wo ni Sáàmù 106:7 kọ́ wa nípa jíjẹ́ olóye? [w95 9/1 ojú ìwé 19, ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 20, ìpínrọ̀ 2]
Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Sáàmù 110:1, 4, ìbúra wo ni Jèhófà ṣe fún Irú Ọmọ náà tàbí Mèsáyà, báwo sì ni èyí ṣe yọrí sí ìbùkún fún gbogbo aráyé? [cl ojú ìwé 194, ìpínrọ̀ 13]
. Nígbà tí onísáàmù náà ṣàṣàrò lórí àǹfààní tó wà nínú sísin Ọlọ́run, kí ni èyí mú kó ṣe? (Sm. 116:12, 14) [w09 7/15 ojú ìwé 29, ìpínrọ̀ 4 sí 5]