ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 February ojú ìwé 31
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ṣé Ò Ń Bójú Tó “Apata Ńlá Ti Ìgbàgbọ́” Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?
    Jí!—2008
  • Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀mí
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 February ojú ìwé 31
Ẹ́sírà mú àkájọ ìwé dání, ó sì ń yin Jèhófà níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí tí Bíbélì fi máa ń tún àwọn ọ̀rọ̀ kan sọ?

NÍGBÀ míì, àwọn tó kọ Bíbélì máa ń tún àwọn ọ̀rọ̀ kan sọ léraléra gẹ́lẹ́ bó ṣe wà. Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan mẹ́ta tó ṣeé ṣe kó mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀:

Ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì. Nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò ní Ìwé Òfin tara wọn. Ìgbà tí gbogbo wọn bá kóra jọ sí àgọ́ ìjọsìn ni wọ́n máa ń gbọ́ bí wọ́n ṣe ń ka Ìwé Òfin yẹn sókè. (Diu. 31:10-12) Ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan kan mú kí wọ́n má pọkàn pọ̀ torí pé ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n máa ń lò níbẹ̀, èrò sì máa ń pọ̀ gan-an. (Neh. 8:2, 3, 7) Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, tí wọ́n bá tún àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Òfin yẹn sọ, ó máa rọrùn fáwọn èèyàn náà láti rántí, kí wọ́n sì fi í sílò. Torí náà, bí wọ́n ṣe ń tún àwọn ọ̀rọ̀ kan sọ léraléra máa jẹ́ káwọn èèyàn náà rántí àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì, irú bí àwọn ìlànà àtàwọn ìdájọ́ Jèhófà.—Léf. 18:4-22; Diu. 5:1.

Bí wọ́n ṣe kọ Bíbélì. Nǹkan bí ìdá mẹ́wàá nínú àwọn ìwé Bíbélì ló jẹ́ orin, irú bí ìwé Sáàmù, Orin Sólómọ́nì àti Ìdárò. Nígbà míì, orin máa ń ní àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ lásọtúnsọ, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó rọrùn fáwọn tó ń gbọ́ orin náà láti há a sórí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 115:9-11, ó ní: “Ísírẹ́lì, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà—Òun ni olùrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn. Ilé Áárónì, ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà—Òun ni olùrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn. Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà—Òun ni olùrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.” Ẹ ò rí i pé bí wọ́n ṣe tún àwọn ọ̀rọ̀ orin yẹn sọ máa jẹ́ kí òtítọ́ pàtàkì inú orin náà wọ àwọn akọrin yẹn lọ́kàn!

Wọ́n fẹ́ tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì. Nígbà míì, àwọn tó kọ Bíbélì máa ń tún ọ̀rọ̀ pàtàkì sọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, léraléra ló ní kí Mósè sọ ìdí tí wọn ò fi gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí tí Ọlọ́run fi ní kó sọ ọ́ léraléra ni pé ó fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé inú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí wà, ìyẹn ni pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí. (Léf. 17:11, 14) Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà táwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbààgbà ní Jerúsálẹ́mù ń sọ àwọn nǹkan tó yẹ ká yẹra fún ká lè múnú Ọlọ́run dùn, wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé a gbọ́dọ̀ sá fún ẹ̀jẹ̀.—Ìṣe 15:20, 29.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan léraléra nínú Bíbélì, ìyẹn ò sọ pé Jèhófà fẹ́ ká sọ ọ́ dàṣà láti máa tún àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ léraléra. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Tí o bá ń gbàdúrà, má sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.” (Mát. 6:7) Lẹ́yìn ìyẹn, ó sọ àwọn nǹkan tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu tó yẹ ká máa gbàdúrà nípa ẹ̀. (Mát. 6:9-13) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ ká máa sọ àsọtúnsọ tá a bá ń gbàdúrà, a ṣì lè bá Jèhófà sọ àwọn ọ̀rọ̀ tá a ti bá a sọ tẹ́lẹ̀ léraléra.—Mát. 7:7-11.

Torí náà, ó dáa bí Bíbélì ṣe tún àwọn ọ̀rọ̀ kan sọ léraléra. Ó wà lára àwọn ọ̀nà tí Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá ń gbà kọ́ wa ká lè ṣe ara wa láǹfààní.—Àìsá. 48:17, 18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́