ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 29:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 “Ohun tí o máa ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́ kí wọ́n lè di àlùfáà mi nìyí: Mú ọmọ akọ màlúù kan, àgbò méjì tí kò ní àbùkù,+ 2 búrẹ́dì aláìwú, búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n pò mọ́ òróró, tó rí bí òrùka àti búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ tí wọ́n fi òróró pa.+ Ìyẹ̀fun àlìkámà* tó kúnná ni kí o fi ṣe wọ́n.

  • Ẹ́kísódù 29:40, 41
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 40 Kí o fi ọmọ àgbò àkọ́kọ́ rúbọ pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí: ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* tí o pò mọ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì* òróró tí wọ́n fún àti ọrẹ ohun mímu tó jẹ́ wáìnì tó kún ìlàrin òṣùwọ̀n hínì. 41 Kí o fi ọmọ àgbò kejì rúbọ ní ìrọ̀lẹ́,* pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti ọrẹ ohun mímu kan náà bíi ti àárọ̀. Kí o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn,* ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.

  • Léfítíkù 2:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 “‘Tí ẹnì* kan bá fẹ́ mú ọrẹ ọkà+ wá fún Jèhófà, kó jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná, kó da òróró sórí rẹ̀, kó sì fi oje igi tùràrí sórí rẹ̀.+

  • Léfítíkù 9:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Lẹ́yìn náà, ó mú ọrẹ ọkà+ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀, ó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun tó sun ní àárọ̀.+

  • Nọ́ńbà 28:4, 5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Kí o mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan wá ní àárọ̀, kí o sì mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kejì wá ní ìrọ̀lẹ́,*+ 5 pẹ̀lú ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* tí wọ́n pò mọ́ òróró tí wọ́n fún tó jẹ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì* láti fi ṣe ọrẹ ọkà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́