8 “Kí o wá mú àwọn ọmọ rẹ̀ wá síwájú, kí o sì wọ aṣọ fún wọn,+ 9 kí o fi àwọn ọ̀já náà di Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lámùrè, kí o sì wé aṣọ sí wọn lórí; àwọn ni yóò máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà, kí èyí jẹ́ ìlànà tó máa wà títí láé.+ Bí o ṣe máa sọ Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ di àlùfáà nìyí.+