43 “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ,+ kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ 44 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín,+ kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí yín,+
9 Nítorí àkójọ òfin tó sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ o ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ o ò gbọ́dọ̀ jalè,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò”+ àti àṣẹ míì tó bá wà, ni a kó pọ̀ sínú ọ̀rọ̀ yìí, pé: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”+