29 “Àṣẹ tó máa wà fún yín títí lọ ni: Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù keje, kí ẹ pọ́n ara yín lójú, ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan,+ ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì tó ń gbé láàárín yín. 30 Ọjọ́ yìí ni wọ́n á ṣe ètùtù+ fún yín láti kéde pé ẹ jẹ́ mímọ́. Ẹ máa di mímọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín níwájú Jèhófà.+