-
Léfítíkù 23:27-31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 “Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni Ọjọ́ Ètùtù.+ Kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́, kí ẹ pọ́n ara yín* lójú,+ kí ẹ sì ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. 28 Ẹ má ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ yìí gangan, torí ó jẹ́ ọjọ́ ètùtù tí wọ́n á ṣe ètùtù+ fún yín níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín. 29 Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni* tí kò bá pọ́n ara rẹ̀ lójú* ní ọjọ́ yìí, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+ 30 Ẹnikẹ́ni* tó bá ṣiṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà, ṣe ni màá pa á run kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 31 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Àṣẹ tí gbogbo ìran yín á máa pa mọ́ títí lọ ni, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
-