-
Hébérù 9:24-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Torí Kristi ò wọnú ibi mímọ́ tí wọ́n fi ọwọ́ ṣe,+ tó jẹ́ àpẹẹrẹ ohun gidi,+ àmọ́ ọ̀run gangan ló wọ̀ lọ,+ tó fi jẹ́ pé ó ń fara hàn báyìí níwájú* Ọlọ́run nítorí wa.+ 25 Kò ṣe èyí láti máa fi ara rẹ̀ rúbọ léraléra bí ìgbà tí àlùfáà àgbà máa ń wọ ibi mímọ́ lọ́dọọdún+ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ tí kì í ṣe tiẹ̀. 26 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ì bá máa jìyà léraléra látìgbà ìpìlẹ̀ ayé. Àmọ́ ní báyìí, ó ti fi ara rẹ̀ hàn kedere ní ìparí àwọn ètò àwọn nǹkan,* lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó fi ara rẹ̀ rúbọ kó lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.+
-