-
Diutarónómì 29:22-24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 “Tí ìran àwọn ọmọ yín lọ́jọ́ iwájú àti àwọn àjèjì tó wá láti ọ̀nà jíjìn bá rí àwọn àjálù tó bá ilẹ̀ náà, àwọn ìyọnu tí Jèhófà mú wá sórí rẹ̀, 23 ìyẹn, imí ọjọ́, iyọ̀ àti iná, kí wọ́n má bàa fúnrúgbìn kankan sí gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ tàbí kí irúgbìn hù níbẹ̀, kí ewéko kankan má sì hù níbẹ̀, bí ìparun Sódómù àti Gòmórà,+ Ádímà àti Sébóímù,+ tí Jèhófà fi ìbínú àti ìrunú rẹ̀ pa run, 24 àwọn àti gbogbo orílẹ̀-èdè máa sọ pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí?+ Kí ló fa ìbínú tó le, tó kàmàmà yìí?’
-
-
Jeremáyà 18:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Gbogbo ẹni tó bá ń gba ibẹ̀ kọjá á wò ó, ẹ̀rù á bà á, á sì mi orí rẹ̀.+
-
-
Ìsíkíẹ́lì 5:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Wọ́n á gàn ọ́, wọ́n á sì fi ọ́ ṣẹlẹ́yà.+ Wọ́n á kọ́gbọ́n lára rẹ, ẹ̀rù á sì ba àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, nígbà tí mo bá fi ìbínú àti ìrunú dá ọ lẹ́jọ́ tí mo sì fìyà jẹ ọ́ gidigidi. Èmi, Jèhófà, ti sọ ọ́.
-