-
Léfítíkù 27:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Tó bá jẹ́ ẹran aláìmọ́,+ tí kò bójú mu ló mú wá láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà, kó mú kí ẹran náà dúró níwájú àlùfáà. 12 Kí àlùfáà wá díye lé e, bó bá ṣe dáa tàbí bó ṣe burú sí. Iye tí àlùfáà bá dá lé e ni yóò jẹ́.
-
-
Léfítíkù 27:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Tó bá jẹ́ ẹ̀yìn ọdún Júbílì ló ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́, kí àlùfáà fi iye ọdún tó ṣẹ́ kù kí ọdún Júbílì tó ń bọ̀ tó dé ṣírò owó rẹ̀ fún un, kó sì yọ kúrò nínú iye tí wọ́n dá lé e.+
-