-
Jẹ́nẹ́sísì 8:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Nóà sì mọ pẹpẹ+ kan fún Jèhófà, ó mú lára gbogbo ẹran tó mọ́ àti lára gbogbo ẹ̀dá tó ń fò+ tó sì mọ́, ó sì rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ náà.+ 21 Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ òórùn dídùn.* Jèhófà wá sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Mi ò tún ní fi ilẹ̀+ gégùn-ún* mọ́ torí èèyàn, torí pé kìkì ibi ni èèyàn ń rò lọ́kàn láti ìgbà èwe rẹ̀ wá;+ mi ò sì tún ní pa gbogbo ohun alààyè run mọ́, bí mo ti ṣe.+
-
-
Nọ́ńbà 15:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí màá fún yín pé kí ẹ máa gbé+ 3 tí ẹ sì mú nínú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran láti fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, ì bàá jẹ́ ẹbọ sísun+ tàbí ẹbọ tí ẹ rú láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí ọrẹ àtinúwá+ tàbí ọrẹ tí ẹ mú wá nígbà àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà+ yín láti mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà,+
-