10 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Áárónì, Nádábù àti Ábíhù,+ mú ìkóná wọn, kálukú fi iná sínú rẹ̀, wọ́n sì fi tùràrí+ sórí rẹ̀. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rú ẹbọ tí kò yẹ+ níwájú Jèhófà, ohun tí kò pa láṣẹ fún wọn. 2 Ni iná bá bọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì jó wọn run,+ wọ́n sì kú níwájú Jèhófà.+