28 Fa iṣẹ́ lé Jóṣúà lọ́wọ́,+ kí o fún un ní ìṣírí, kí o sì mú un lọ́kàn le, torí òun ló máa kó àwọn èèyàn yìí sọdá,+ òun ló sì máa mú kí wọ́n jogún ilẹ̀ tí wàá rí.’
14 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! Ọjọ́ ikú rẹ ti sún mọ́lé.+ Pe Jóṣúà, kí ẹ sì lọ síwájú* àgọ́ ìpàdé, kí n lè faṣẹ́ lé e lọ́wọ́.”+ Mósè àti Jóṣúà wá lọ síwájú àgọ́ ìpàdé.
23 Lẹ́yìn náà, Ó* fa iṣẹ́ lé Jóṣúà+ ọmọ Núnì lọ́wọ́, ó sọ pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ torí ìwọ lo máa mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ tí mo búra fún wọn nípa rẹ̀,+ mi ò sì ní fi ọ́ sílẹ̀.”