6 Ẹbọ sísun ìgbà gbogbo+ ni, èyí tí a fi lélẹ̀ ní Òkè Sínáì láti mú òórùn dídùn jáde, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, 7 pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀, ìlàrin òṣùwọ̀n hínì fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn+ kọ̀ọ̀kan. Da ohun mímu tó ní ọtí náà sínú ibi mímọ́ láti fi ṣe ọrẹ ohun mímu fún Jèhófà.