-
Nọ́ńbà 4:24-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Iṣẹ́ tí ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì á máa ṣe àtàwọn ohun tí wọ́n á máa gbé+ nìyí: 25 Kí wọ́n máa gbé aṣọ àgọ́+ ti àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé, ìbòrí rẹ̀ àti ìbòrí tí wọ́n fi awọ séálì ṣe tó wà lókè rẹ̀,+ aṣọ* tí wọ́n ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,+ 26 àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí àgbàlá,+ aṣọ* tí wọ́n ta sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá+ tó yí àgọ́ ìjọsìn àti pẹpẹ ká, àwọn okùn àgọ́ wọn àti gbogbo ohun èlò wọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe nìyí.
-