8 Jèhófà tún sọ fún Áárónì pé: “Èmi fúnra mi fi gbogbo ọrẹ tí wọ́n bá ṣe fún mi+ sí ìkáwọ́ rẹ. Mo ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lára gbogbo ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fi ṣe ọrẹ, kó jẹ́ ìpín+ yín títí lọ.
19 Gbogbo ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá fún Jèhófà+ ni mo ti fún ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ pẹ̀lú rẹ, kó jẹ́ ìpín+ yín títí lọ. Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀* tó máa wà títí lọ níwájú Jèhófà fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ.”