ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 14:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Àmọ́ torí pé ẹ̀mí tí Kélẹ́bù+ ìránṣẹ́ mi ní yàtọ̀, tó sì ń fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé mi, ó dájú pé màá mú un wá sí ilẹ̀ tó lọ, yóò sì di ti+ àtọmọdọ́mọ rẹ̀.

  • Diutarónómì 1:34-38
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 “Ní gbogbo ìgbà yẹn, Jèhófà gbọ́ ohun tí ẹ̀ ń sọ, inú sì bí i gidigidi, ó wá búra pé,+ 35 ‘Ìkankan nínú àwọn èèyàn yìí tí wọ́n wà lára ìran búburú yìí kò ní rí ilẹ̀ dáradára tí mo búra pé màá fún àwọn bàbá yín,+ 36 àfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè. Òun máa rí i, mo sì máa fún òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní ilẹ̀ tó rìn lórí rẹ̀, torí pé ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé Jèhófà.*+ 37 (Torí yín ni Jèhófà tiẹ̀ ṣe bínú sí mi, ó ní, “Ìwọ náà ò ní wọ ibẹ̀.+ 38 Jóṣúà ọmọ Núnì, tó máa ń dúró níwájú rẹ+ ló máa wọ ilẹ̀ náà.+ Sọ ọ́ di alágbára,*+ torí òun ló máa mú kí Ísírẹ́lì jogún rẹ̀.”)

  • Jóṣúà 14:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin mi tí a jọ lọ mú kí ọkàn àwọn èèyàn wa domi,* mo fi gbogbo ọkàn mi tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run mi.*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́