-
Nọ́ńbà 14:28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Sọ fún wọn pé, ‘“Ó dájú pé bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà wí, “ohun tí mo gbọ́ tí ẹ sọ+ gẹ́lẹ́ ni màá ṣe sí yín!
-
-
Nọ́ńbà 14:35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 “‘“Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀. Ohun tí màá ṣe fún àwọn èèyàn burúkú yìí tí wọ́n kóra jọ láti ta kò mí nìyí: Inú aginjù yìí ni wọ́n máa ṣègbé sí, ibí ni wọ́n sì máa kú sí.+
-
-
Nọ́ńbà 32:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Inú bí Jèhófà gidigidi ní ọjọ́ yẹn débi tó fi búra+ pé: 11 ‘Àwọn ọkùnrin tó kúrò ní Íjíbítì, láti ẹni ogún (20) ọdún sókè kò ní rí ilẹ̀ + tí mo búra pé màá fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù,+ torí pé wọn ò fi gbogbo ọkàn wọn tọ̀ mí lẹ́yìn, 12 àfi Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè ọmọ Kénásì àti Jóṣúà+ ọmọ Núnì, torí pé wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn tọ Jèhófà lẹ́yìn.’+
-
-
Diutarónómì 2:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ọdún méjìdínlógójì (38) la fi rìn láti Kadeṣi-bánéà títí a fi sọdá Àfonífojì Séréédì, títí gbogbo ìran àwọn ọkùnrin ogun fi pa run láàárín àpéjọ, bí Jèhófà ṣe búra fún wọn gẹ́lẹ́.+
-
-
Sáàmù 95:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Torí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé:
“Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi.”+
-