29 Yàtọ̀ síyẹn, Mósè pín ogún fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ìdajì nínú ẹ̀yà Mánásè ní ìdílé-ìdílé.+ 30 Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Máhánáímù+ tó fi mọ́ gbogbo Báṣánì, gbogbo ilẹ̀ Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo abúlé Jáírì+ tí wọ́n pàgọ́ sí ní Báṣánì, ó jẹ́ ọgọ́ta (60) ìlú.