-
Nọ́ńbà 4:34-36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Mósè àti Áárónì àti àwọn ìjòyè+ àpéjọ náà wá forúkọ àwọn ọmọ Kóhátì+ sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 35 gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.+ 36 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (2,750).+
-