24 Ẹ ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run wọn, ẹ má sì jẹ́ kí wọ́n mú kí ẹ sìn wọ́n, ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí ẹ wó wọn palẹ̀, kí ẹ sì run àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn.+
5 “Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ máa ṣe sí wọn nìyí: Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ sì wó àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn,+ ẹ gé àwọn òpó òrìṣà* wọn,+ kí ẹ sì dáná sun àwọn ère gbígbẹ́ wọn.+
3 Kí ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, kí ẹ fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn túútúú,+ kí ẹ dáná sun àwọn òpó òrìṣà* wọn, kí ẹ sì gé ère àwọn ọlọ́run wọn+ tí wọ́n gbẹ́ lulẹ̀, kí orúkọ wọn lè pa rẹ́ kúrò níbẹ̀.+