-
Nọ́ńbà 27:1-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Àwọn ọmọ Sélóféhádì+ wá sí tòsí, Sélóféhádì yìí ni ọmọ Héfà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírù, ọmọ Mánásè, látọ̀dọ̀ àwọn ìdílé Mánásè ọmọ Jósẹ́fù. Orúkọ àwọn ọmọ Sélóféhádì ni Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà. 2 Wọ́n dúró síwájú Mósè, àlùfáà Élíásárì, àwọn ìjòyè+ àti gbogbo àpéjọ náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, wọ́n sì sọ pé: 3 “Bàbá wa ti kú ní aginjù, àmọ́ kò sí lára àwọn tó gbìmọ̀ pọ̀ láti ta ko Jèhófà, àwọn tó ti Kórà+ lẹ́yìn. Torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ló ṣe kú, kò sì ní ọmọkùnrin kankan. 4 Kí ló dé tí orúkọ bàbá wa fi máa pa rẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ torí pé kò bímọ ọkùnrin? Fún wa ní ohun ìní láàárín àwọn arákùnrin bàbá wa.” 5 Mósè wá mú ọ̀rọ̀ wọn tọ Jèhófà+ lọ.
6 Jèhófà sọ fún Mósè pé: 7 “Òótọ́ làwọn ọmọ Sélóféhádì sọ. Rí i pé o fún wọn ní ohun ìní tí wọ́n lè jogún láàárín àwọn arákùnrin bàbá wọn, kí o sì mú kí ogún bàbá wọn di tiwọn.+
-