16 Àtọmọdọ́mọ àwọn Kénì,+ tó jẹ́ bàbá ìyàwó Mósè+ pẹ̀lú àwọn èèyàn Júdà wá láti ìlú ọlọ́pẹ+ sí aginjù Júdà, tó wà ní gúúsù Árádì.+ Wọ́n lọ síbẹ̀, wọ́n sì ń gbé láàárín àwọn èèyàn náà.+
11 Ó ṣẹlẹ̀ pé Hébà ará Kénì ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn Kénì,+ àwọn àtọmọdọ́mọ Hóbábù, bàbá ìyàwó+ Mósè, ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí tòsí igi ńlá ní Sáánánímù, tó wà ní Kédéṣì.
6 Sọ́ọ̀lù wá sọ fún àwọn Kénì pé:+ “Ẹ jáde kúrò láàárín àwọn ọmọ Ámálékì, kí n má bàa gbá yín lọ pẹ̀lú wọn.+ Nítorí ẹ fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì+ nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Íjíbítì.” Torí náà, àwọn Kénì kúrò ní àárín àwọn ọmọ Ámálékì.