-
Nọ́ńbà 8:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 “Èyí kan àwọn ọmọ Léfì: Kí ẹni tó bá ti pé ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.
-
-
Nọ́ńbà 18:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Kí o tún mú àwọn arákùnrin rẹ tí wọ́n jẹ́ ara ẹ̀yà Léfì sún mọ́ tòsí, ẹ̀yà baba ńlá rẹ, kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ ọ, kí wọn sì máa bá ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ṣiṣẹ́+ níwájú àgọ́ Ẹ̀rí.+ 3 Kí wọ́n máa ṣe ojúṣe wọn fún ọ àti fún àgọ́ náà lódindi.+ Àmọ́, wọn ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ àwọn ohun èlò ibi mímọ́ àti pẹpẹ kí ẹ̀yin tàbí àwọn má bàa kú.+
-
-
1 Kíróníkà 23:32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Wọ́n tún ń ṣe ojúṣe wọn ní àgọ́ ìpàdé àti ní ibi mímọ́. Wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọmọ Áárónì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà.
-