-
Nọ́ńbà 4:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Wọn ò gbọ́dọ̀ wọlé wá wo àwọn ohun mímọ́, ì báà jẹ́ fírí, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n máa kú.”+
-
-
Nọ́ńbà 16:39, 40Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
39 Àlùfáà Élíásárì wá kó àwọn ìkóná tí wọ́n fi bàbà ṣe, èyí tí àwọn tó jóná náà mú wá, ó sì fi wọ́n rọ ohun tí wọ́n á fi máa bo pẹpẹ, 40 bí Jèhófà ṣe gbẹnu Mósè sọ fún un. Yóò máa rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé ẹnikẹ́ni tí kò tọ́ sí,* tí kì í ṣe ọmọ Áárónì kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti sun tùràrí níwájú Jèhófà+ àti pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ dà bíi Kórà àti àwọn tó ń tì í lẹ́yìn.+
-