-
Nọ́ńbà 3:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Ojúṣe àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ nínú àgọ́ ìpàdé ni pé kí wọ́n máa bójú tó àgọ́ ìjọsìn àti àgọ́,*+ ìbòrí rẹ̀,+ aṣọ* tí wọ́n ta+ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, 26 àwọn aṣọ ìdábùú+ tí wọ́n ta sí àgbàlá, aṣọ* tí wọ́n ta+ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá tó yí àgọ́ ìjọsìn àti pẹpẹ ká, àwọn okùn àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí.
-
-
Nọ́ńbà 3:36, 37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
36 Ojúṣe àwọn ọmọ Mérárì ni pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn férémù+ àgọ́ ìjọsìn, àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀,+ àwọn òpó rẹ̀,+ àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀, gbogbo ohun èlò+ rẹ̀ àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí,+ 37 títí kan àwọn òpó tó yí àgbàlá náà ká àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò+ wọn, èèkàn àgọ́ wọn àti okùn àgọ́ wọn.
-