-
Ẹ́kísódù 30:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 “Kí o ṣe pẹpẹ kan láti máa fi sun tùràrí;+ igi bọn-ọ̀n-ní ni kí o fi ṣe é.+ 2 Kó ní igun mẹ́rin tó dọ́gba, ìgbọ̀nwọ́* kan ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì. Kí pẹpẹ náà àti àwọn ìwo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan.+ 3 Kí o fi ògidì wúrà bò ó lókè pẹ̀lú ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yí ká àti àwọn ìwo rẹ̀; kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká.
-