38 Mósè àti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló pàgọ́ síwájú àgọ́ ìjọsìn lápá ìlà oòrùn, níwájú àgọ́ ìpàdé lápá ibi tí oòrùn ti ń yọ. Ojúṣe wọn sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni pé kí wọ́n máa bójú tó ibi mímọ́. Tí ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i bá sún mọ́ tòsí, ṣe ni wọ́n máa pa á.+