23 “‘Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ló lé àwọn Ámórì kúrò níwájú Ísírẹ́lì èèyàn rẹ̀,+ ṣé o wá fẹ́ lé wọn kúrò ni? 24 Ṣebí ohunkóhun tí Kémóṣì+ ọlọ́run rẹ bá fún ọ pé kí o gbà lo máa ń gbà? Torí náà gbogbo àwọn tí Jèhófà Ọlọ́run wa bá lé kúrò níwájú wa la máa lé kúrò.+
7 Ìgbà náà ni Sólómọ́nì kọ́ ibi gíga+ kan fún Kémóṣì, ọlọ́run ìríra Móábù, lórí òkè tó wà níwájú Jerúsálẹ́mù, ó sì tún kọ́ òmíràn fún Mólékì,+ ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Ámónì.+
13 Ọba sọ àwọn ibi gíga tó wà níwájú Jerúsálẹ́mù di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, èyí tó wà ní gúúsù* Òkè Ìparun,* tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì mọ fún Áṣítórétì abo ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Sídónì; fún Kémóṣì ọlọ́run ìríra Móábù àti fún Mílíkómù+ ọlọ́run ẹ̀gbin àwọn ọmọ Ámónì.+