-
Nọ́ńbà 22:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Wọ́n wá sọ́dọ̀ Báláámù, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ohun tí Bálákì ọmọ Sípórì sọ nìyí, ‘Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ọ lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, 17 torí màá dá ọ lọ́lá gan-an, ohunkóhun tí o bá sì ní kí n ṣe ni màá ṣe. Torí náà, jọ̀ọ́ máa bọ̀, wá bá mi gégùn-ún fún àwọn èèyàn yìí.’”
-
-
Nọ́ńbà 24:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Inú wá bí Bálákì sí Báláámù gan-an. Bálákì wá fi ìbínú pàtẹ́wọ́, ó sì sọ fún Báláámù pé: “Torí kí o lè gégùn-ún fún àwọn ọ̀tá mi ni mo ṣe pè ọ́ + wá, àmọ́ ṣe lo kàn ń súre fún wọn lẹ́ẹ̀mẹta yìí. 11 Ó yá, tètè pa dà sílé. Mo fẹ́ dá ọ lọ́lá gan-an+ tẹ́lẹ̀ ni, àmọ́ wò ó! Jèhófà ò jẹ́ kí n dá ọ lọ́lá.”
-