-
Nọ́ńbà 23:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Bálákì wá sọ fún Báláámù pé: “Kí lo ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá kí o lè gégùn-ún fún àwọn ọ̀tá mi, àmọ́ ṣe lo kàn wá ń súre fún wọn.”+
-
-
Nehemáyà 13:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n ka ìwé Mósè sétí àwọn èèyàn,+ wọ́n sì rí i pé ó wà lákọsílẹ̀ pé àwọn ọmọ Ámónì àti àwọn ọmọ Móábù+ kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Ọlọ́run tòótọ́ láé,+ 2 nítorí wọn kò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní oúnjẹ àti omi, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n háyà Báláámù láti gégùn-ún fún wọn.+ Àmọ́, Ọlọ́run wa yí ègún náà pa dà sí ìbùkún.+
-