-
Nọ́ńbà 22:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Móábù wá sọ fún àwọn àgbààgbà Mídíánì+ pé: “Ìjọ yìí máa jẹ gbogbo ohun tó wà ní àyíká wa run, bí akọ màlúù ṣe máa ń jẹ ewéko inú pápá run.”
Bálákì ọmọ Sípórì ni ọba Móábù nígbà yẹn. 5 Ó ní kí àwọn ìránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Báláámù ọmọ Béórì ní Pétórì,+ èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Odò* ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Ó sọ pé kí wọ́n pè é wá, ó ní: “Wò ó! Àwọn èèyàn kan ti wá láti Íjíbítì. Wò ó! Wọ́n bo ilẹ̀,*+ iwájú mi gan-an ni wọ́n sì ń gbé. 6 Torí náà, jọ̀ọ́ wá bá mi gégùn-ún+ fún àwọn èèyàn yìí, torí wọ́n lágbára jù mí lọ. Bóyá màá lè ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ náà, torí ó dá mi lójú pé ẹni tí o bá súre fún máa rí ìbùkún gbà, ègún sì máa wà lórí ẹni tí o bá gégùn-ún fún.”
-