34 Mósè wá kúrò ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù lọ sí Òkè Nébò,+ sí orí Písígà,+ tó dojú kọ Jẹ́ríkò.+ Jèhófà sì fi gbogbo ilẹ̀ náà hàn án, láti Gílíádì títí dé Dánì+
4 Jèhófà sọ fún un pé: “Ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù nìyí pé, ‘Ọmọ* rẹ ni èmi yóò fún.’+ Mo ti jẹ́ kí o fi ojú ara rẹ rí i, àmọ́ o ò ní sọdá sí ibẹ̀.”+