6 Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú,+ tó ń gba tẹni rò,*+ tí kì í tètè bínú,+ tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ àti òtítọ́*+ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,
3 nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú+ pa dà wá, ó máa ṣàánú+ rẹ, ó sì máa kó ọ jọ látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí.
9 Torí ìgbà tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà ni àwọn arákùnrin yín àti àwọn ọmọ yín máa rí àánú gbà látọ̀dọ̀ àwọn tó mú wọn lẹ́rú,+ wọ́n á sì jẹ́ kí wọ́n pa dà sí ilẹ̀ yìí,+ nítorí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò* àti aláàánú,+ kò sì ní yí ojú rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ yín tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀.”+