-
Jóṣúà 20:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ní agbègbè Jọ́dánì, lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò, wọ́n yan Bésérì+ ní aginjù tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú* látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Rámótì+ ní Gílíádì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Gádì àti Gólánì+ ní Báṣánì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Mánásè.+
9 Àwọn ìlú yìí ni wọ́n yàn fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn àjèjì tó ń gbé láàárín wọn, kí ẹnikẹ́ni tó bá ṣèèṣì pa èèyàn* lè sá lọ síbẹ̀,+ kí ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má bàa pa á kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú àpéjọ náà.+
-