ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 20:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 “O ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnìkejì rẹ.+

  • Ẹ́kísódù 23:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 “O ò gbọ́dọ̀ tan ìròyìn èké kálẹ̀.*+ Má ṣe lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ẹni burúkú láti jẹ́rìí èké.+

  • Léfítíkù 19:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 “‘O ò gbọ́dọ̀ máa bani lórúkọ jẹ́ káàkiri láàárín àwọn èèyàn rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ dìde lòdì sí ẹ̀mí* ẹnì kejì rẹ.*+ Èmi ni Jèhófà.

  • Diutarónómì 19:16-19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Tí ẹlẹ́rìí èké kan bá jẹ́rìí lòdì sí ẹnì kan, tó sì fẹ̀sùn kàn án pé ó ṣe ohun tí kò dáa,+ 17 kí àwọn méjèèjì tó ń bára wọn fa ọ̀rọ̀ wá dúró níwájú Jèhófà, níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí wọ́n á máa dájọ́ nígbà yẹn.+ 18 Kí àwọn adájọ́ náà wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa,+ tó bá jẹ́ ẹlẹ́rìí èké ni ẹni tó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà, tó sì fẹ̀sùn èké kan arákùnrin rẹ̀, 19 ohun tó gbèrò láti ṣe sí arákùnrin rẹ̀ ni kí ẹ ṣe sí i,+ kí ẹ sì mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+

  • Òwe 6:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Ohun mẹ́fà wà tí Jèhófà kórìíra;

      Bẹ́ẹ̀ ni, ohun méje tó jẹ́ ohun ìríra fún un:*

  • Òwe 6:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Ẹlẹ́rìí èké tí kò lè ṣe kó má parọ́+

      Àti ẹni tó ń dá awuyewuye sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.+

  • Òwe 19:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,+

      Ẹni tí kò sì lè ṣe kó má parọ́ kò ní yè bọ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́