-
Hébérù 12:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ẹ sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pátápátá, tó fi bá yín sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé: “Ọmọ mi, má fojú kéré ìbáwí látọ̀dọ̀ Jèhófà,* má sì sọ̀rètí nù nígbà tó bá tọ́ ọ sọ́nà; 6 torí àwọn tí Jèhófà* nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí, àní, gbogbo ẹni tó gbà bí ọmọ ló máa ń nà lẹ́gba.”*+
7 Ẹ nílò ìfaradà bí ẹ ṣe ń gba ìbáwí.* Ọlọ́run mú yín bí ọmọ.+ Torí ọmọ wo ni bàbá kì í bá wí?+
-