26 O lè wá fi owó náà ra ohunkóhun tó bá wù ọ́,* bíi màlúù, àgùntàn, ewúrẹ́, wáìnì àtàwọn ohun mímu míì tó ní ọtí àti ohunkóhun tí o bá fẹ́;* kí o jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì máa yọ̀, ìwọ àti agbo ilé rẹ.+
66 Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e,* ó ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn, inú wọn ń dùn, ayọ̀ sì kún ọkàn wọn nítorí gbogbo oore+ tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Ísírẹ́lì àwọn èèyàn rẹ̀.
10 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ, ẹ jẹ àwọn ohun tó dọ́ṣọ̀,* ẹ mu àwọn ohun dídùn, kí ẹ sì fi oúnjẹ ránṣẹ́+ sí àwọn tí kò ní nǹkan kan; nítorí ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́ lójú Olúwa wa, ẹ má sì banú jẹ́, nítorí ìdùnnú Jèhófà ni ibi ààbò* yín.”