-
Diutarónómì 17:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “Tí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ ní ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ, tí ẹjọ́ náà sì ṣòroó dá, bóyá ọ̀rọ̀ nípa ìtàjẹ̀sílẹ̀+ tàbí ẹnì kan fẹ́ gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ tàbí àwọn kan hùwà ipá tàbí àwọn ẹjọ́ míì tó jẹ mọ́ fífa ọ̀rọ̀, kí o gbéra, kí o sì lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yàn.+ 9 Lọ bá àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì àti adájọ́+ tó ń gbẹ́jọ́ nígbà yẹn, kí o ro ẹjọ́ náà fún wọn, wọ́n á sì bá ọ dá a.+
-