16 “Ní ìwòyí ọ̀la, màá rán ọkùnrin kan láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì sí ọ.+ Kí o fòróró yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì,+ yóò sì gba àwọn èèyàn mi lọ́wọ́ àwọn Filísínì. Nítorí mo ti rí ìpọ́njú àwọn èèyàn mi, igbe ẹkún wọn sì ti dé ọ̀dọ̀ mi.”+
5 Àwọn Filísínì pẹ̀lú kóra jọ láti bá Ísírẹ́lì jà, wọ́n ní ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) agẹṣin àti àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ bí iyanrìn etí òkun;+ wọ́n jáde lọ, wọ́n sì tẹ̀ dó sí Míkímáṣì ní ìlà oòrùn Bẹti-áfénì.+