19 Sámúẹ́lì dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Èmi ni aríran náà. Máa gòkè lọ níwájú mi sí ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí.+ Màá jẹ́ kí ẹ máa lọ láàárọ̀ ọ̀la, màá sì sọ gbogbo ohun tí o fẹ́ mọ̀* fún ọ.
27 Ọba wá sọ fún àlùfáà Sádókù pé: “Ṣebí aríran+ ni ọ́? Pa dà sínú ìlú ní àlàáfíà, kí o mú àwọn ọmọ yín méjèèjì dání, Áhímáásì ọmọ rẹ àti Jónátánì+ ọmọ Ábíátárì.
22 Gbogbo àwọn tí wọ́n yàn ṣe aṣọ́bodè ní àwọn ibi àbáwọlé jẹ́ igba ó lé méjìlá (212). Wọ́n wà ní ibi tí wọ́n tẹ̀ dó sí bí orúkọ wọn ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.+ Dáfídì àti Sámúẹ́lì aríran+ ló yàn wọ́n sí ipò ẹni tó ṣeé fọkàn tán tí wọ́n wà.