Sáàmù 37:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Fi ìbínú sílẹ̀, kí o sì pa ìrunú tì;+Má ṣe bínú kí o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ibi.* Òwe 15:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́* máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀,+Àmọ́ ọ̀rọ̀ líle* ń ru ìbínú sókè.+ Oníwàásù 7:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Má ṣe máa yára* bínú,+ torí pé àyà àwọn òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.*+